Orin Dafidi 60:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun, o ti kọ̀ wá sílẹ̀,o ti wó odi wa;o ti bínú, dákun, mú wa bọ̀ sípò.

2. O ti mú kí ilẹ̀ mì tìtì;o ti mú kí ó yanu;dí gbogbo ibi tí ilẹ̀ ti ya, nítorí pé ó ń mì.

3. O ti jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ ní ọpọlọpọ ìnira,o ti fún wa ní ọtí mu tóbẹ́ẹ̀ tí à ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

Orin Dafidi 60