2. Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò,iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé.
3. Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,tí wọn ń purọ́.
4. Wọ́n ní oró bí oró ejò,wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,
5. kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,tabi ìpè adáhunṣe.
6. Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun.
7. Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.
8. Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí.
9. Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ.
10. Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké,yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú.
11. Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé,“Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo;nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.”