Orin Dafidi 58:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́?

2. Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò,iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé.

3. Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,tí wọn ń purọ́.

4. Wọ́n ní oró bí oró ejò,wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,

Orin Dafidi 58