Orin Dafidi 55:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ìparun wà ninu rẹ̀;ìnilára ati ìwà èrú kò sì kúrò láàrin ìgboro rẹ̀.

12. Bí ó bá ṣe pé ọ̀tá ní ń gàn mí,ǹ bá lè fara dà á.Bí ó bá ṣe pé ẹni tí ó kórìíra mi ní ń gbéraga sí mi,ǹ bá fara pamọ́ fún un.

13. Ṣugbọn ìwọ ni; ìwọ tí o jẹ́ irọ̀ mi,alábàárìn mi, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́.

14. À ti jọ máa sọ ọ̀rọ̀ dídùndídùn pọ̀ rí;a sì ti jọ rìn ní ìrẹ́pọ̀ ninu ilé Ọlọrun.

Orin Dafidi 55