Orin Dafidi 54:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Fi agbára orúkọ rẹ gbà mí, Ọlọrun,fi ipá rẹ dá mi láre.

2. Gbọ́ adura mi, Ọlọrun;tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.

3. Nítorí pé àwọn agbéraga dìde sí mi,àwọn ìkà, aláìláàánú sì ń lépa ẹ̀mí mi;wọn kò bìkítà fún Ọlọrun.

4. Ṣugbọn Ọlọrun ni olùrànlọ́wọ́ mi,OLUWA ni ó gbé ẹ̀mí mi ró.

Orin Dafidi 54