Orin Dafidi 52:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìwọ alágbára, kí ló dé tí o fi ń fọ́nnu,kí ló dé tí ò ń fọ́nnu tọ̀sán-tòru?Ẹni ìtìjú ni ọ́ lójú Ọlọrun.

2. Ò ń pète ìparun;ẹnu rẹ dàbí abẹ tí ó mú, ìwọ alárèékérekè.

3. O fẹ́ràn ibi ju ire lọ,o sì fẹ́ràn irọ́ ju òtítọ́ lọ.

4. O fẹ́ràn gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́,Ìwọ ẹlẹ́tàn!

Orin Dafidi 52