1. Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA;kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi.
2. Fetí sí igbe mi,Ọba mi ati Ọlọrun mi,nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.
3. OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀,ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ;èmi óo sì máa ṣọ́nà.
4. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú;àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé.
5. Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ;o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi.