Orin Dafidi 48:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ninu tẹmpili rẹ, Ọlọrun,à ń ṣe àṣàrò lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

10. Ọlọrun, ìyìn rẹ tàn ká,bí orúkọ rẹ ṣe tàn dé òpin ayé,iṣẹ́ rere kún ọwọ́ rẹ.

11. Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,kí gbogbo Juda sì máa yọ̀nítorí ìdájọ́ rẹ.

12. Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀;

13. ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀

14. pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,lae ati laelae.Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.”

Orin Dafidi 48