11. Jẹ́ kí inú òkè Sioni kí ó dùn,kí gbogbo Juda sì máa yọ̀nítorí ìdájọ́ rẹ.
12. Ẹ rìn yí Sioni po; ẹ yí i ká;ẹ ka àwọn ilé ìṣọ́ rẹ̀;
13. ẹ ṣàkíyèsí odi rẹ̀;ẹ wọ inú gbogbo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lọ,kí ẹ lè ròyìn fún ìran tí ń bọ̀
14. pe: “Ọlọrun yìí ni Ọlọrun wa,lae ati laelae.Òun ni yóo máa ṣe amọ̀nà wa títí lae.”