1. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;ẹ kọ orin ayọ̀, ẹ hó sí Ọlọrun.
2. Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo,Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3. Ó tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba fún wa,ó sì sọ àwọn orílẹ̀-èdè di àtẹ̀mọ́lẹ̀ fún wa.
4. Òun ni ó yan ilẹ̀ ìní wa fún wa,èyí tí àwọn ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀, fi ń yangàn.
5. A ti gbé Ọlọrun ga pẹlu ìhó ayọ̀,a ti gbé OLUWA ga pẹlu ìró fèrè.