Orin Dafidi 44:19-22 BIBELI MIMỌ (BM)

19. sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20. Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,tabi tí a bá bọ oriṣa,

21. ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.

22. Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà.

Orin Dafidi 44