Orin Dafidi 4:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,Ọlọrun mi olùdániláre.Ìwọ ni o yọ mí nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ṣàánú mi, kí o sì gbọ́ adura mi.

2. Ẹ̀yin ọmọ eniyan, yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo máa fi ojú ọlá mi gbolẹ̀,tí ẹ óo máa fẹ́ràn ọ̀rọ̀ asán, tí ẹ óo sì máa wá irọ́ kiri?

Orin Dafidi 4