12. Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi,wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru.
13. Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́,mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀.
14. Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀,tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu.
15. Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè;OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn.
16. Nítorí tí mò ń gbadura pé,kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mínígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.
17. Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo.