1. OLUWA, má fi ibinu bá mi wí!Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà!
2. Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára,ọwọ́ rẹ sì ti bà mí.
3. Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara minítorí ibinu rẹ;kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi,nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4. Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀;ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlátí ó wúwo jù fún mi.
5. Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn,nítorí ìwà òmùgọ̀ mi,
6. Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru.
7. Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi.
8. Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi.
9. OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ.