Orin Dafidi 36:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀ṣẹ̀ ń gbin lọ́kàn eniyan burúkú,kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ninu èrò tirẹ̀.

2. Nítorí pé lọ́kàn rẹ̀ a máa pọ́n ara rẹ̀,pé kò sí ẹni tí ó lè rí ẹ̀ṣẹ̀ òun,ká tó wá sọ pé yóo dá òun lẹ́bi.

3. Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀.Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró;kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.

Orin Dafidi 36