2. OLUWA ni èmi óo máa fi yangàn;kí inú àwọn olùpọ́njú máa dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́.
3. Ẹ bá mi gbé OLUWA ga,ẹ jẹ́ kí á jùmọ̀ gbé orúkọ rẹ̀ lékè!
4. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù.
5. Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀;ojú kò sì tì wọ́n.
6. Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀,ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7. Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká,a sì máa gbà wọ́n.