Orin Dafidi 34:16-22 BIBELI MIMỌ (BM)

16. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára,láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé.

17. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́,a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn.

18. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́,a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.

19. Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀;ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.

20. A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́;kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn.

21. Ibi ni yóo pa eniyan burúkú;a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi.

22. OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada;ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.

Orin Dafidi 34