Orin Dafidi 32:8-11 BIBELI MIMỌ (BM)

8. N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn;n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn;n óo sì máa mójútó ọ.

9. Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka,tí kò ni ọgbọ́n ninu,tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nukí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀.

10. Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú,ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká.

11. Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA;ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo;kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.

Orin Dafidi 32