Orin Dafidi 31:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú;mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò.

13. Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi,tí wọ́n sì ń pète ati pa mí;wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.

14. Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA,Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”

15. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi,ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.

16. Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ,gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

17. Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA,nítorí ìwọ ni mò ń ké pè.Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú;jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì.

18. Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi,àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo.

19. Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ otí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan,fún àwọn tí ó sá di ọ́.

20. O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n;o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan;o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ,kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.

21. Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu,ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí,nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́.

Orin Dafidi 31