5. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé,yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀,lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí;yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta.
6. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gunlórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká;n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀,n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.
7. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́;ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn.
8. Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.”Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA,
9. má fi ojú pamọ́ fún mi!”Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò,ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́,má ta mí nù, má sì ṣá mi tì,Ọlọrun ìgbàlà mi.