Orin Dafidi 23:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ni Olùṣọ́-aguntan mi,n kò ní ṣe àìní ohunkohun.

2. Ó mú mi dùbúlẹ̀ ninu pápá koríko tútù,ó mú mi lọ sí ibi tí omi ti dákẹ́ rọ́rọ́;

3. ó sọ agbára mi dọ̀tun.Ó tọ́ mi sí ọ̀nà òdodonítorí orúkọ rẹ̀.

4. Àní, bí mo tilẹ̀ ń rìn ninu òkùnkùn létí bèbè ikú,n kò ní bẹ̀rù ibi kankan;nítorí tí o wà pẹlu mi;ọ̀gọ rẹ ati ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.

Orin Dafidi 23