Orin Dafidi 2:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń bínú fùfùtí àwọn eniyan ń gbìmọ̀ asán?

2. Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ,àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀,wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.

3. Wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á fa ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dè wá jákí á sì yọ ara wa kúrò lóko ẹrú wọn.”

4. Ẹni tí ó gúnwà lọ́run ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín;OLUWA sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.

5. Lẹ́yìn náà, yóo sọ̀rọ̀ sí wọn ninu ibinu rẹ̀,yóo dẹ́rùbà wọ́n gidigidi ninu ìrúnú rẹ̀,

Orin Dafidi 2