8. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
9. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omini ó fi ṣe ìbòrí.
12. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,láti inú ìkùukùu.
13. OLUWA sán ààrá láti ọ̀run,Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde.
14. Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká,ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.
15. Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete,ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA,ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ.