7. Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì;wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú.
8. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
9. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá,ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò,ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omini ó fi ṣe ìbòrí.
12. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ,ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde,láti inú ìkùukùu.