Orin Dafidi 18:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi,ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi.

19. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè,ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi.

20. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè.

21. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́,n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.

Orin Dafidi 18