11. Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí;wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú.
12. Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ,àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba.
13. Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀;fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
14. OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi;àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí,fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́;jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó;sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ.