1. Ẹ yin OLUWA!Nítorí tí ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọrun wa;nítorí olóore ni, orin ìyìn sì yẹ ẹ́.
2. OLUWA ní ń kọ́ ìlú Jerusalẹmu;òun ni yóo kó àwọn ọmọ Israẹli tí a fọ́n ká jọ.
3. Ó ń tu àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́ ninu,ó sì ń dí ọgbẹ́ wọn.
4. Òun ló mọ iye àwọn ìràwọ̀,òun ló sì fún gbogbo wọn lórúkọ.
5. OLUWA wa tóbi, ó sì lágbára pupọòye rẹ̀ kò ní ìwọ̀n.
6. OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró,òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.
7. Ẹ kọ orin ọpẹ́ sí OLUWA,ẹ fi hapu kọ orin dídùn sí Ọlọrun wa.
8. Ẹni tí ó fi ìkùukùu bo ojú ọ̀run,ó pèsè òjò fún ilẹ̀,ó mú koríko hù lórí òkè.
9. Òun ni ó ń fún àwọn ẹranko ní oúnjẹ,tí ó sì ń bọ́ ọmọ ẹyẹ ìwò, tí ó ń ké.
10. Kì í ṣe agbára ẹṣin ni inú rẹ̀ dùn sí,kì í sì í ṣe inú agbára eniyan ni ayọ̀ rẹ̀ wà.
11. Ṣugbọn inú OLUWA dùn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àwọn tí ó ní ìrètí ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
12. Gbé OLUWA ga, ìwọ Jerusalẹmu!Yin Ọlọrun rẹ, ìwọ Sioni!
13. Ó fún ẹnubodè rẹ ní agbára,ó sì bukun àwọn tí ń gbé inú rẹ.