1. OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2. Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́.
3. OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.
4. Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.