13. Nítorí ìwọ ni o dá inú mi,ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi.
14. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́;ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ!O mọ̀ mí dájú.
15. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀,tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí,kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ.
16. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi,o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún misinu ìwé rẹ,kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
17. Ọlọrun, iyebíye ni èrò rẹ lójú mi!Wọ́n pọ̀ pupọ ní iye.
18. Bí mo bá ní kí n kà wọ́n,wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ;nígbà tí mo bá sì jí,ọ̀dọ̀ rẹ náà ni n óo wà.
19. Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú,kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.
20. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ nípa rẹ,àwọn ọ̀tá rẹ ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
21. OLUWA, mo kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ;mo sì kẹ́gàn àwọn tí ń dìtẹ̀ sí ọ?
22. Mo kórìíra wọn dé òpin;ọ̀tá ni mo kà wọ́n kún.
23. Wádìí mi, Ọlọrun, kí o mọ ọkàn mi;yẹ̀ mí wò, kí o sì mọ èrò ọkàn mi.
24. Wò ó bí ọ̀nà ibi kan bá wà tí mò ń tọ̀,kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà ayérayé.