Orin Dafidi 138:3-6 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ní ọjọ́ tí mo ké pè ọ́, o dá mi lóhùn,o sì fún mi ní agbára kún agbára.

4. OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

5. Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,nítorí pé ògo OLUWA tóbi.

6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.

Orin Dafidi 138