3. nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùnti ní kí á kọrin fún àwọn.Àwọn tí ó ń pọ́n wa lójú sọ pé kí á dá àwọn lárayá, wọ́n ní,“Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.”
4. Báwo ni a óo ṣe kọ orin OLUWA ní ilẹ̀ àjèjì?
5. Jerusalẹmu, bí mo bá gbàgbé rẹ,kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó rọ.
6. Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ èrìgì mi,bí n kò bá ranti rẹ,bí n kò bá sì fi Jerusalẹmu ṣe olórí ayọ̀ mi.
7. OLUWA, ranti ohun tí àwọn ará Edomu ṣenígbà tí Jerusalẹmu bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí wọn ń pariwo pé,“Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o títí dé ìpìlẹ̀ rẹ̀.”
8. Babiloni! Ìwọ apanirun!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ̀san lára rẹ,fún gbogbo ohun tí o ti ṣe sí wa!
9. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá kó àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ,tí ó ṣán wọn mọ́ àpáta.