1. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
2. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí ó ju gbogbo àwọn oriṣa lọ,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
3. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tí ó ju gbogbo àwọn oluwa lọ,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.