4. Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.
5. Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi,ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ.
6. Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣelọ́run ati láyé,ninu òkun ati ninu ibú.
7. Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé,ó fi mànàmáná fún òjò,ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.