1. Ẹ yin OLUWA.Ẹ yin orúkọ OLUWA;ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀,
2. ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA,tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa.
3. Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun;ẹ kọrin ìyìn sí i,nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni.
4. Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀,ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.