Orin Dafidi 131:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, n kò ṣe ìgbéraga,bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè.N ò dáwọ́ lé nǹkan ńláńlá,n ò sì dá àrà tí ó jù mí lọ.

2. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́,bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀.Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́.

Orin Dafidi 131