1. Ninu ìṣòro ńlá ni mò ń ké pè ọ́, OLUWA!
2. OLUWA, gbóhùn mi,dẹtí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
3. Bí OLUWA bá ń sàmì ẹ̀ṣẹ̀,ta ló lè yege?
4. Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà,kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.
5. Mo gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, àní, mo gbé ọkàn mi lé e,mo sì ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀.