1. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLÚWA,tí ó sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀.
2. O óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,ayọ̀ ń bẹ fún ọ, yóo sì dára fún ọ.
3. Aya rẹ yóo dàbí àjàrà eléso pupọ ninu ilé rẹ;bí ọmọ tií yí igi olifi ká,ni àwọn ọmọ rẹ yóo yí tabili oúnjẹ rẹ ká.
4. Wò ó, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA yóo kẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù rẹ̀.