3. Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ó yẹ̀,ẹni tí ń pa ọ́ mọ́ kò ní tòògbé.
4. Wò ó, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́kò ní tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sùn.
5. OLUWA ni olùpamọ́ rẹ.OLUWA yóo ṣíji bò ọ́ ní apá ọ̀tún rẹ.
6. Oòrùn kò ní ṣe ọ́ léṣe lọ́sàn-án,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá kò ní pa ọ́ lára lóru.
7. OLUWA óo dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ibi,yóo pa ọ́ mọ́.
8. OLUWA yóo pa àlọ ati ààbọ̀ rẹ mọ́,láti ìsinsìnyìí lọ ati títí lae.