Orin Dafidi 119:99-102 BIBELI MIMỌ (BM)

99. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.

100. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

101. N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́.

102. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi.

Orin Dafidi 119