96. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.
97. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.
98. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.
99. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.
100. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101. N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́.
102. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi.