94. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
95. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,wọ́n fẹ́ pa mí run,ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.
96. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.
97. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.
98. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.
99. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.
100. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101. N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́.
102. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi.
103. Ọ̀rọ̀ rẹ dùn mọ́ mi pupọ,ó dùn ju oyin lọ.
104. Nípa ẹ̀kọ́ rẹ ni mo fi ní òye,nítorí náà mo kórìíra gbogbo ìwà èké.