Orin Dafidi 119:93-102 BIBELI MIMỌ (BM)

93. Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ,nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé.

94. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí;nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.

95. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí,wọ́n fẹ́ pa mí run,ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

96. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán,àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.

97. Mo fẹ́ràn òfin rẹ lọpọlọpọ!Òun ni mo fi ń ṣe àṣàrò tọ̀sán-tòru.

98. Ìlànà rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí pé òun ni ó ń darí mi nígbà gbogbo.

99. Òye mi ju ti àwọn olùkọ́ mi lọ,nítorí pé ìlànà rẹ ni mo fi ń ṣe àṣàrò.

100. Òye mi ju ti àwọn àgbà lọ,nítorí pé mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.

101. N kò rin ọ̀nà ibi kankan,kí n lè pa òfin rẹ mọ́.

102. N kò yapa kúrò ninu òfin rẹ,nítorí pé o ti kọ́ mi.

Orin Dafidi 119