Orin Dafidi 119:76-92 BIBELI MIMỌ (BM)

76. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ máa tù mí ninu,gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí o ṣe fún èmi, iranṣẹ rẹ.

77. Ṣàánú mi, kí n lè wà láàyè,nítorí pé òfin rẹ ni ìdùnnú mi.

78. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn onigbeeraga,nítorí wọ́n ṣe àrékérekè sí mi láìnídìí;ní tèmi, n óo máa ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ.

79. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ tọ̀ mí wá,kí wọ́n lè mọ òfin rẹ.

80. Níti pípa òfin rẹ mọ́, jẹ́ kí n pé,kí ojú má baà tì mí.

81. Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi;ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ.

82. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi,níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ.Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?”

83. Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì,sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ.

84. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi?

85. Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí,àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́.

86. Gbogbo òfin rẹ ló dájú;ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi.

87. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé,ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀.

88. Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ.

89. OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run.

90. Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran;o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró.

91. Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní,nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.

92. Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi,ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú.

Orin Dafidi 119