4. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,
5. Ìbá ti dára tótí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!
6. Òun ni ojú kò fi ní tì mí,nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.
7. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.
8. N óo máa pa òfin rẹ mọ́,má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.
9. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.
10. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.
11. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.
12. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,kọ́ mi ní ìlànà rẹ!
13. Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.
14. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
15. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.
16. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.