167. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́,mo fẹ́ràn wọn gidigidi.
168. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ;gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí.
169. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA,fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
170. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ,kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
171. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ,pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
172. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ,nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà.
173. Múra láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ.
174. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA;òfin rẹ sì ni inú dídùn mi.
175. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́,sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́.
176. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù;wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí,nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.