Orin Dafidi 119:131-134 BIBELI MIMỌ (BM)

131. Mo la ẹnu, mò ń mí hẹlẹ,nítorí pé mò ń lépa òfin rẹ.

132. Kọjú sí mi kí o ṣe mí lóorebí o ti máa ń ṣesí àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ.

133. Mú ẹsẹ̀ mi dúró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ,má sì jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ kankan jọba lórí mi.

134. Gbà mí lọ́wọ́ ìnilára àwọn eniyan,kí n lè máa tẹ̀lé ìlànà rẹ.

Orin Dafidi 119