115. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi,kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.
116. Gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ, kí n lè wà láàyè,má sì dójú ìrètí mi tì mí.
117. Gbé mi ró, kí n lè wà láìléwu,kí n lè máa ka ìlànà rẹ sí nígbà gbogbo.
118. O ti kọ gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò ninu ìlànà rẹ sílẹ̀,nítorí pé asán ni gbogbo ẹ̀tàn wọn.
119. O ti pa àwọn eniyan burúkú tì, bí ìdàrọ́ irin,nítorí náà ni mo ṣe fẹ́ràn ìlànà rẹ.