1. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
2. Jẹ́ kí Israẹli wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”
3. Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”
4. Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”
5. Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA,ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀.
6. Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí.Kí ni eniyan lè fi mí ṣe?
7. OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mipẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun.