1. Ẹ yin OLUWA!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA,tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀.
2. Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé,a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin.
3. Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀,Òdodo rẹ̀ wà títí lae.
4. Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo.
5. Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan,tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà.
6. A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae,títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀.