2. Iṣẹ́ OLUWA tóbi,àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri.
3. Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo,òdodo rẹ̀ sì wà títí lae.
4. OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀,olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀.
5. A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀,a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae.
6. Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀,nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.
7. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà,gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú.
8. Wọ́n wà títí lae ati laelae,ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin.
9. Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀,ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae,mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀.